Aṣojú-Ṣòfin Abd Kareem Tajudeen Abisọ́dún tí gbogbo ènìyàn mọ sí Wẹ́rẹ́ tí í ṣe alága Ilé Ìgbìmọ̀ lórí Àṣà àti Ìrìnàjò afẹ́, ti ṣe kòkárí ìyípadà ọ̀tún kan lati pinlẹ̀ ríró awọn ọ̀dọ́kùnrin àti ọ̀dọ́bìnrin lágbára ní ẹkùn Ìwọ̀ Oòrùn Ṣakí, Ila Oorun Saki, ati Atisbo.
Ayẹyẹ yìí ti ó wáyé ni Gbọ̀ngàn Ọlọ́pọ̀ Ìṣe Àbẹ̀jẹ́ àti Sàbí ni Ile Iko-nnkan-si Funfunlòògùn ní ìlú Saki ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé gba àwọn akópa lọ́dọ́mọ́kùnrin ati lodomobinrin to lé ní ọgọ́rùn-ún (100) ati awọn obinrin to le ni ogóje (140) lati ẹkun meta otooto.
Ayẹyẹ yìí ló mojuto onírúurú eko nipa iṣẹ-imo, idawole, ati ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ ọ̀sin ẹja ìgbàlódé, rire ẹja dagba, ati didena àrùn tó lè beja jà.

Nígbà tí Aṣojú-Sofin Tajudeen Wẹ́rẹ́ tí Alaaji Sabitu Olofa sójú rẹ n ba àwọn akópa yii sọrọ, tọka sí ipa pataki eto ẹkọ yìí
“Afojusun wa ni lati kún awọn ọ̀dọ́ lára pẹlu ọgbọn àti ìmọ tó wúlò tí o le jẹ kí ìgbé-aye idẹrun bá wọn” Wẹ́rẹ́ ló sọ eleyii.
“Kìí ṣe owó nìkan ni ènìyàn lè fi owo ọsin ẹja pa, sugbon Osin eja tun pese ounjẹ si niluu ati mu idagba sókè dé bá àwùjọ.”
Awọn onimọ to to gbangba sun lọ́yẹ́ lori osin eja ló ṣe idalekoo to jinle l’ori onírúurú ẹkọ nipa osin eja. Awọn akópa ni wọn kọ bí ènìyàn se le bẹrẹ iṣẹ ọ̀sìn eja, lilo omi tó toro ati ọna ìṣàkóso to lọ́ọ̀rin.
Eto naa ṣe àkóónú abala ọrọ ajé osin ẹja, bi ase le se àkóso káràkátà rẹ̀ ati agbọn ìṣúná owó.
Ni àfikún, Aṣoju-sofin Tajudeen Wẹ́rẹ́ kéde ìpèsè ohun elo pàtàkì lati fi bẹrẹ fún àwọn akópa ati Ebun owó láti fi bẹrẹ iṣẹ ọsin eja náà.
Atilẹyin yìí ni láti mú idiwọ kuro ati lati le rí i dájú pé wọn ṣe amulo ẹkọ tí wọn kọ.
Aṣojú-Sofin Abd Kareem Tajudeen Abisọ́dún Wẹ́rẹ́ Pin ẹ̀rọ ilota fún àwọn obìnrin ní ẹkùn idibo rẹ. Agbekale yìí ni láti ran idile kọọkan lọwọ lasiko làásìgbo eto ọrọ̀ ajé ti orilẹ-ede yìí nkoju.
Awọn akópa kọọkan lo gba ẹrọ ilota yii, pẹlu èròngbà lati fẹju awon okoowo keekeke ati láti tún ìgbé-aye àwọn ọmọ ìlú ṣe. Ọnà tó gbòòrò láti ran ìṣúná owó tí n ṣe segesege lọwọ ni asiko ipenija eto ọrọ̀ ajé yìí ni ọgbọn àtinúda yii jẹ́.